Mark 15:33-41

Ikú Jesu

33 aNígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34 bNí wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, Lama Sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).

35Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Elijah.”

36 cNígbà náà ni ẹnìkan sáré lọ ki kànìnkànìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jesu kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Elijah yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀ wa.”

37Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.

38 dAṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. 39 eNígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe.”

40 fÀwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome. 41 gÀwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

Copyright information for YorBMYO